James 5:1-3

Ìkìlọ̀ fún àwọn aninilára ọlọ́rọ̀

1Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. 2Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. 3Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.
Copyright information for YorBMYO